Revelation 7:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.” Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú Ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà.