Revelation 7:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí èyí ni wọ́n ṣe wà níwájú ìtẹ́ Ọlọrun, tí wọn ń júbà tọ̀sán-tòru ninu Tẹmpili rẹ̀. Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà yóo máa bá wọn gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni nwọn ṣe mbẹ niwaju itẹ́ Ọlọrun, ti nwọn si nsìn i li ọsán ati li oru ninu tẹmpili rẹ̀: ẹniti o joko lori itẹ́ na yio si ṣiji bò wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ni, “wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run, tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹḿpílì rẹ̀; ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn.