Revelation 7:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo bá tún rí angẹli mìíràn tí ó gòkè wá láti ìhà ìlà oòrùn, tí ó mú èdìdì Ọlọrun alààyè lọ́wọ́. Ó kígbe lóhùn rara sí àwọn angẹli mẹrẹẹrin tí a fún ní agbára láti ṣe ayé ní jamba.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si ri angẹli miran ti o nti ìha ìla-õrùn goke wá, ti on ti èdidi Ọlọrun alãye lọwọ: o si kigbe li ohùn rara si awọn angẹli mẹrin na ti a fifun lati pa aiye ati okun lara,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì rí ańgẹ́lì mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-òòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́: ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn ańgẹ́lì mẹ́rin náà tí a fifún un láti pa ayé, àti òkun, lára,