Revelation 8:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo tún rí ìran yìí. Mo gbọ́ tí idì kan tí ń fò ní agbede meji ọ̀run ń kígbe pé, “Ó ṣe! Ó ṣe! Ó ṣe fún gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé orí ilẹ̀ ayé nígbà tí kàkàkí tí àwọn angẹli mẹta yòókù fẹ́ fun bá dún!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wò, mo si gbọ́ idì kan ti nfò li ãrin ọrun, o nwi li ohùn rara pe, Egbé, egbé, egbé, fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye nitori ohùn ipè iyoku ti awọn angẹli mẹta ti mbọwá fun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo sì wò, mo sì gbọ́ idí kan tí ń fò ni àárin ọ̀run, ó ń wí lóhùn rara pé, “Ègbé, ègbé, fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé nítorí ohun ìpè ìyókù tí àwọn ańgẹ́lì mẹ́ta tí ń bọ̀ wá yóò fún!”