Revelation 8:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ekinni fun kàkàkí rẹ̀. Ni yìnyín ati iná pẹlu ẹ̀jẹ̀ bá tú dà sórí ilẹ̀ ayé. Ìdámẹ́ta ayé bá jóná, ati ìdámẹ́ta àwọn igi ati gbogbo koríko tútù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ekini si fun, yinyín ati iná ti o dàpọ̀ pẹlu ẹ̀jẹ si jade, a si dà wọn sori ilẹ aiye: idamẹta ilẹ aiye si jóna, idamẹta awọn igi si jóna, ati gbogbo koriko tutù si jóna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀: Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ̀ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ̀ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jónà.