Revelation 9:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ní ìrù bíi ti àkeekèé tí wọ́n fi lè ta eniyan. A fún wọn ní agbára ninu ìrù wọn láti ṣe eniyan léṣe fún oṣù marun-un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ni ìru ati oró bi ti akẽkẽ, ati ni ìru wọn ni agbara wọn wà lati pa enia lara fun oṣù marun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún.