Revelation 9:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí àwọn ẹṣin ọ̀hún ati àwọn tí ó gùn wọ́n ti rí lójú mi, lójú ìran nìyí: wọ́n gba ọ̀já ìgbàyà tí ó pọ́n bí iná, ó dàbí àyìnrín, ó tún rí bí imí-ọjọ́. Orí àwọn ẹṣin náà dàbí orí kinniun. Wọ́n ń yọ iná, ati èéfín ati imí-ọjọ́ lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni mo si ri awọn ẹṣin na li ojuran, ati awọn ti o gùn wọn; nwọn ni awo ìgbaiya iná, ati ti jakinti, ati ti imí ọjọ: ori awọn ẹṣin na si dabi ori awọn kiniun; ati lati ẹnu wọn ni iná, ati ẹ̃fin, ati imí ọjọ ti njade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jàkìntì, àti tí súfúrù: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìninún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti súfúrù tí ń jáde.