Revelation 9:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Agbára àwọn ẹṣin wọnyi wà ní ẹnu wọn ati ní ìrù wọn. Nítorí ìrù wọn dàbí ejò, wọ́n ní orí. Òun sì ni wọ́n fi ń ṣe àwọn eniyan léṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe agbara awọn ẹṣin na mbẹ li ẹnu wọn ati ni iru wọn: nitoripe ìru wọn dabi ejò, nwọn si ni ori, awọn wọnyi ni nwọn si fi npa-ni-lara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: Nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pani lára.