Romans 1:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò yẹ kí ẹ má mọ̀, ará, pé ní ìgbà pupọ ni mo ti fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, kí n lè ní èso láàrin yín bí mo ti ní láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, ṣugbọn nǹkankan ti ń dí mi lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ títí di àkókò yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ará, emi kò si fẹ ki ẹnyin ki o ṣe alaimọ̀ pe, nigba-pupọ li emi npinnu rẹ̀ lati tọ̀ nyin wá (ṣugbọn o di ẹtì fun mi di isisiyi,) ki emi ki o le ni eso diẹ ninu nyin pẹlu, gẹgẹ bi lãrin awọn Keferi iyokù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá, (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrin yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in láàrin àwọn aláìkọlà yóòkù.