Romans 1:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò tijú ìyìn rere Jésù, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún aláìkọlà pẹ̀lú.