Romans 1:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìlò obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìsìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí.