Romans 1:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí á tó máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nípasẹ̀ Jesu Kristi nítorí gbogbo yín; nítorí àwọn eniyan ń ròyìn igbagbọ yín ní gbogbo ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo kọ́ dupẹ na lọwọ Ọlọrun mi nipasẹ Jesu Kristi nitori gbogbo nyin, nitoripe a nròhin igbagbọ́ nyin yi gbogbo aiye ká.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkọ́kọ́, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Jésù kírísítì fún gbogbo yín, nítorí a ń ròyìn ìgbàgbọ́ yin káàkiri gbogbo ayé.