Romans 10:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo wá ń bèèrè, “Ṣé wọn kò ì tíì gbọ́ ni?” Wọ́n kúkú ti gbọ́, nítorí a rí i kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Ìró wọn ti dé gbogbo orílẹ̀-èdè, àní, ọ̀rọ̀ wọn ti dé òpin ayé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn mo ni, Nwọn kò ha gbọ́ bi? Bẹni nitõtọ, Ohùn wọn jade lọ si gbogbo ilẹ, ati ọ̀rọ wọn si opin ilẹ aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mo ní, wọn kò ha gbọ́ bí? Bẹ́ẹ̀ ni nítòótọ́: “Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀, àti ọ̀rọ̀ wọn sí òpin ayé.”