Romans 10:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo tún bèèrè: Àbí Israẹli kò mọ̀ ni? Ẹ jẹ́ kí á gbọ́ ohun tí Mose kọ́kọ́ sọ; ó ní, “N óo jẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe orílẹ̀-èdè mu yín jowú, N óo sì jẹ́ kí orílẹ̀-èdè tí kò lóye mú kí ara ta yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn mo ni, Israeli kò ha mọ̀ bi? Mose li o kọ́ wipe, Emi o fi awọn ti kì iṣe enia mu nyin jowú, ati awọn alaimoye enia li emi o fi bi nyin ninu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n mo wí pé, Ísírẹ́lì kò ha mọ̀ bí? Mósè ni ó kọ́ wí pé, “Èmi ó fi àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mú yín jowú. Àti àwọn aláìmòye ènìyàn ni èmi ó fi bí yín nínú.”