Romans 10:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò tíì ní òye ọ̀nà tí Ọlọrun fi ń dáni láre, nítorí náà wọ́n wá ọ̀nà ti ara wọn, wọn kò sì fi ara wọn sábẹ́ ètò tí Ọlọrun ṣe fún ìdániláre.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi nwọn kò ti mọ ododo Ọlọrun, ti nwọn si nwá ọna lati gbé ododo ara wọn kalẹ, nwọn kò tẹriba fun ododo Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdí ni pé, wọ́n ń gbìyànjú láti hu ìwà rere nípa pípa òfin àti àṣà ìbílẹ̀ àwọn Júù mọ́, kí wọn báà lè rí ojú rere Ọlọ́run. Kò yé wọn pé, Kírísítì ti kú láti mú wọn dọ́gba pẹ̀lú Ọlọ́run. Òfin àwọn Júù àti àṣà ìbílẹ̀ wọn kì í ṣe ọ̀nà tí Ọlọ́run lè fi gba ènìyàn là.