Romans 11:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ǹjẹ́ bí ìṣìnà wọn bá ṣe ayé ní anfaani, bí ìkùnà wọn bá ṣe orílẹ̀-èdè yòókù ní anfaani, báwo ni anfaani náà yóo ti pọ̀ tó nígbà tí gbogbo wọn bá ṣe ojúṣe wọn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi iṣubu wọn ba di ọrọ̀ aiye, ati bi ifasẹhin wọn ba di ọrọ̀ awọn Keferi; melomelo ni kíkún wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá ṣe pé gbogbo ayé di ọlọ́rọ̀ nípa ìgbàlà tí Ọlọ́run fifún àwọn Júù nítorí pé wọ́n kọ ìgbàlà náà, ìbùkún tí ó tóbi jùlọ ni yóò tún jẹ́ fún wa nígbà tí àwọn Júù fúnra wọn yóò tún ní ìgbàlà náà pẹ̀lú wa.