Romans 11:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí bí kíkọ̀ tí Ọlọrun kọ̀ wọ́n sílẹ̀ bá mú kí aráyé bá Ọlọrun rẹ́, kí ni yóo ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọlọrun bá gbà wọ́n mọ́ra? Ǹjẹ́ òkú pàápàá kò ní jí dìde?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi titanù wọn ba jẹ ìlaja aiye, gbigbà wọn yio ha ti ri, bikoṣe iyè kuro ninu okú?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun ìyanu ni yóò jẹ́ nígbà tí àwọn Júù yóò di Kírísítẹ́nì. Nígbà tí Ọlọ́run yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ṣe ni ó yípadà sí àwọn ìyókù ní ayé (àwọn aláìkọlà) láti fún wọn ní ìgbàlà. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú nísinsinyí ìyanu náà ń peléke sí i ni nígbà tí àwọn Júù bá wá sọ́dọ̀ Kírísítì. Bí ẹni pé a sọ àwọn òkú di alààyè ni yóò jẹ́.