Romans 11:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí a bá ya ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ rí ninu ìkórè sí mímọ́, a ti ya burẹdi tí a fi ṣe sí mímọ́. Bí a bá ya gbòǹgbò igi sí mímọ́, a ti ya àwọn ẹ̀ka igi náà sí mímọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi akọso ba mọ́, bẹ̃li akopọ: bi gbòngbo ba si mọ́, bẹ si li awọn ẹ̀ka rẹ̀ na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n ìgbà tí Ábúráhámù àti àwọn wòlíì jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run pẹ̀lú. Ìdí ni pé, bí gbòǹgbò igi bá jẹ́ mímọ́, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò jẹ́ mímọ́ pẹ̀lú.