Romans 11:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Máṣe ṣe fefé si awọn ẹ̀ka na. Ṣugbọn bi iwọ ba nṣe fefé, iwọ kọ́ li o rù gbòngbo, ṣugbọn gbòngbo li o rù iwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣe gbéraga nítorí pé a fi yín sí ipò àwọn ẹ̀ka tí a ké kúrò. Nǹkan tí ó mú kí ẹ ṣe pàtàkì ni pé, ẹ jẹ́ ẹ̀ka igi Ọlọ́run yìí. Ẹ rántí pé, ẹ̀ka igi lásán ni yín, ẹ kì í ṣe gbòngbò.