Romans 11:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà ṣe akiyesi ìyọ́nú Ọlọrun ati ìrorò rẹ̀. Ó rorò sí àwọn tí ó kùnà. Yóo yọ́nú sí ọ, tí o bá farabalẹ̀ gba ìyọ́nú rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo gé ìwọ náà kúrò pẹlu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina wo ore ati ikannu Ọlọrun: lori awọn ti o ṣubu, ikannu; ṣugbọn lori iwọ, ore, bi iwọ ba duro ninu ore rẹ̀: ki a má ba ke iwọ na kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà wo ore àti ìkáànú Ọlọ́run lórí àwọn tí ó subú, ìkàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, ọrẹ, bi ìwọ bá dúró nínú ọrẹ rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò.