Romans 11:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn Juu tí a gé kúrò yóo tún bọ́ sí ipò wọn pada, bí wọn bá kọ ọ̀nà aigbagbọ sílẹ̀. Ọlọrun lágbára láti tún lọ́ wọn pada sí ibi tí ó ti gé wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn pẹlu, bi nwọn kò ba joko sinu aigbagbọ́, a o lọ́ wọn sinu rẹ̀: nitori Ọlọrun le tún wọn lọ́ sinu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀.