Romans 11:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìwọ tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi olifi tí ó la ilẹ̀ hù ninu ìgbẹ́, tí a lọ́ mọ́ ara igi olifi inú oko, tí ẹ̀dá wọn yàtọ̀ sí ara wọn, báwo ni yóo ti rọrùn tó láti tún lọ́ àwọn tí ó jẹ́ ara igi olifi inú oko tẹ́lẹ̀ mọ́ ara igi tí a ti gé wọn kúrò!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi a ti ke iwọ kuro lara igi oróro igbẹ́ nipa ẹda, ti a si lọ́ iwọ sinu igi oróro rere lodi si ti ẹda: melomelo li a o lọ́ awọn wọnyi, ti iṣe ẹka-iyẹka sara igi oróro wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí a bá ti ke ìwọ kúrò lára igi ólífì ìgbẹ́ nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì gbé ìwọ lé orí igi ólífì rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòómélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi ólífì wọn?