Romans 11:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ ohun àṣírí yìí, kí ẹ má baà ro ara yín jù bí ó ti yẹ lọ. Òun ni pé, apá kan ninu àwọn ọmọ Israẹli yóo jẹ́ alágídí ọkàn títí di ìgbà tí iye àwọn tí a yàn láti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo fi dé ọ̀dọ̀ Ọlọrun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ará, emi kò sá fẹ ki ẹnyin ki o wà li òpe niti ohun ijinlẹ yi, ki ẹnyin má ba ṣe ọlọ́gbọn li oju ara nyin; pe ifọju bá Israeli li apakan, titi kíkún awọn Keferi yio fi de.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ará, èmi kò sá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má baá ṣe ọlọgbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Ísírẹ̀lì ní apákan, títí kíkún àwọn aláìkọlà yóò fi dé.

Recommended Reading