Romans 11:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Tí ó bá wá jẹ́ pé nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni Ọlọrun fi yàn wọ́n, kò tún lè jẹ́ nítorí iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, oore-ọ̀fẹ́ kò ní jẹ́ oore-ọ̀fẹ́ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o ba si ṣepe nipa ti ore-ọfẹ ni, njẹ kì iṣe ti iṣẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, ore-ọfẹ kì iṣe ore-ọfẹ mọ́. Ṣugbọn biobaṣepe nipa ti iṣẹ́ ni, njẹ kì iṣe ti ore-ọfẹ mọ́: bi bẹ̃ kọ́, iṣẹ kì iṣe iṣẹ mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
í ó bá sì ṣe pé nípa ti ore-ọ̀fẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti iṣẹ́ mọ́; àyàmọ̀bí ore-ọ̀fẹ́ kì í ṣe ore-ọ̀fẹ́ mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pe nípa ti iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ kì í ṣe ti ore-ọ̀fẹ́ mọ́; àyàmọ̀bí iṣẹ́ kì í ṣe iṣẹ́ mọ́.