Romans 11:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi náà sọ pé, “Jẹ́ kí àsè wọn di tàkúté ati àwọ̀n, kí ó gbé wọn ṣubú, kí ó mú ẹ̀san bá wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wipe, Jẹ ki tabili wọn ki o di idẹkun, ati ẹgẹ́, ati ohun ikọsẹ, ati ẹsan fun wọn:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun kan náà yìí ni Dáfídì ọba sọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé: “Kí oúnjẹ àti àwọn nǹkan mèremère wọn tàn wọ́n, láti rò pé wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run. Jẹ́ kí àwọn nǹkan wọ̀nyí padà dojú ìjà kọ wọ́n, kí a bá à lè fi òtítọ́ wó wọn túútúú.