Romans 12:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin olùfẹ́, ẹ má máa gbẹ̀san, dípò bẹ́ẹ̀, ẹ máa fún Ọlọrun láàyè láti fi ibinu rẹ̀ hàn. Nítorí Ọlọrun sọ ninu àkọsílẹ̀ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olufẹ, ẹ máṣe gbẹsan ara nyin, ṣugbọn ẹ fi àye silẹ fun ibinu; nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Temi li ẹsan, emi ó gbẹsan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Olùfẹ́, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Èmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.”