Romans 12:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí ẹ para dà, kí ọkàn yín di titun, kí ẹ lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ má sì da ara yín pọ̀ mọ́ ayé yìí; ṣùgbọ́n kí ẹ paradà láti di titun ní ìrò-inú yín, kí ẹ̀yin kí ó lè rí ìdí ìfẹ́ Ọlọ́run, tí ó dára, tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà, ti ó sì pé.