Romans 12:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí nípa oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi, mò ń sọ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan láàrin yín pé kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ jù bí ó ti yẹ lọ. Ṣugbọn kí olukuluku ronú níwọ̀n, kí ó máa ṣe jẹ́jẹ́, níwọ̀nba bí Ọlọrun ti pín ẹ̀bùn igbagbọ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wà ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o máṣe rò ara rẹ̀ jù bi o ti yẹ ni rirò lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntun-wọnsìn, bi Ọlọrun ti fi ìwọn igbagbọ́ fun olukuluku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ̀ntún-wọ̀nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olukúkùlù.