Romans 13:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
KI olukuluku ọkàn ki o foribalẹ fun awọn alaṣẹ ti o wà ni ipo giga. Nitori kò si aṣẹ kan, bikoṣe lati ọdọ Ọlọrun wá: awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun li a ti làna rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí olúkúlùkù ọkàn kí ó foríbalẹ̀ fún àwọn aláṣẹ tí ó wà ní ipò gíga. Nítorí kò sí àṣẹ kan, bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá; àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run li a ti lànà rẹ̀ wá.