Romans 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ san ohun tí ẹ bá jẹ ẹnikẹ́ni pada fún un. Ẹ san owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí. Ẹ san owó-odè fún ẹni tí owó-odè yẹ. Ẹ bu ọlá fún ẹni tí ọlá bá yẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ san ohun ti o tọ fun ẹni gbogbo: owo-ode fun ẹniti owo-ode iṣe tirẹ̀: owo-bode fun ẹniti owo-bode iṣe tirẹ̀; ẹ̀ru fun ẹniti ẹ̀ru iṣe tirẹ̀; ọlá fun ẹniti ọlá iṣe tirẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ san ohun tí ó tọ́ fún ẹni gbogbo: owó-orí fún ẹni tí owó-orí tọ́ sí: owó-bodè fún ẹni tí owó-bodè tọ́ sí: ẹ̀rù fún ẹni tí ẹ̀rù ń ṣe tirẹ̀; ọlá fún ẹni tí ọlá ń ṣe tirẹ̀