Romans 13:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Fẹ́ràn ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ” ni kókó òfin bíi, “Má ṣe àgbèrè, má jalè, má ṣe ojúkòkòrò,” ati èyíkéyìí tí ó kù ninu òfin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi, Iwọ kò gbọdọ ṣe panṣaga, Iwọ kò gbọdọ pania, Iwọ kò gbọdọ jale, Iwọ kò gbọdọ jẹri eke, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro; bi ofin miran ba si wà, a ko o pọ ninu ọ̀rọ yi pe, Fẹran ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panságà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ sọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.”