Romans 14:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí ni ìdí tí o fi ń dá arakunrin rẹ lẹ́jọ́? Sọ ọ́ kí á gbọ́! Tabi kí ló dé tí ò ń fi ojú tẹmbẹlu arakunrin rẹ? Gbogbo wa mà ni a óo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọrun!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẽṣe ti iwọ fi nda arakunrin rẹ lẹjọ? tabi ẽsitiṣe ti iwọ fi nkẹgan arakunrin rẹ? gbogbo wa ni yio sá duro niwaju itẹ́ idajọ Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èése nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arakùnrin rẹ lẹ́jọ́? tàbì èése tí ìwọ sì ń fi ojú ẹ̀gàn wo arakùnrin rẹ? Nítorí olúkúlùkù wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.