Romans 14:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ìpinnu kan tí à bá ṣe ni pé, kí á má ṣe fi ohun ìkọsẹ̀ kan, tabi ohunkohun tí yóo ṣi arakunrin wa lọ́nà, sí ojú ọ̀nà rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yé dá ara wa lẹ́jọ́. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má se fi òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arakùnrin yín.