Romans 14:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ìwọ bá ní igbagbọ ní tìrẹ, jẹ́ kí igbagbọ tí o ní wà láàrin ìwọ ati Ọlọrun rẹ. Olóríire ni ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò bá dá lẹ́bi lórí nǹkan tí ó bá gbà láti ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ní igbagbọ́ bi? ní i fun ara rẹ niwaju Ọlọrun. Alabukun-fun ni oluwarẹ̀ na ti ko da ara rẹ̀ lẹbi ninu ohun ti o yàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ohun tí ìwọ bá gbàgbọ́ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí, pa á mọ́ ní àárín ìwọ àti Ọlọ́run. Alábùkún fún ni ẹni náà tí kò dá ara rẹ̀ lẹ́bi nípa ohun tí ohun gbà.