Romans 14:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ tí kì í se tìrẹ lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun ni dúró, tàbí subú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.