Romans 14:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori idi eyi na ni Kristi ṣe kú, ti o si tún yè, ki o le jẹ Oluwa ati okú ati alãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìdí èyí náà ni Kírísítì fi kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààye.