Romans 15:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N kò jẹ́ sọ nǹkankan àfi àwọn nǹkan tí Kristi tọwọ́ mi ṣe, láti mú kí àwọn tí wọn kì í ṣe Juu lè gbọ́ràn sí Ọlọrun. Mo ṣe àwọn nǹkan wọnyi nípa ọ̀rọ̀ ati ìṣe mi,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi kò sá gbọdọ sọ ohun kan ninu eyi ti Kristi kò ti ọwọ́ ṣe, si igbọran awọn Keferi nipa ọ̀rọ ati iṣe,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kò sa à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò se èyí tí Kírisítì ti ọwọ́ mi se, ní títọ́ àwọn aláìkọlà sọ́nà láti ṣe ìgbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi: