Romans 15:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti parí iṣẹ́ mi ní gbogbo agbègbè yìí. Bí mo sì ti ní ìfẹ́ fún ọdún pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín, mo lérò láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi bi emi kò ti li àye mọ́ li ẹkùn wọnyi, bi emi si ti fẹ gidigidi lati ọdún melo wọnyi lati tọ̀ nyin wá,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ ní agbègbè yìí, tí èmi sì ti ń pòùngbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti tọ̀ yín wá,