Romans 15:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo yà sọ́dọ̀ yín nígbà tí mo bá ń kọjá lọ sí Spania. Ìrètí mi ni láti ri yín, kí ẹ lè ràn mí lọ́wọ́, kí n lè débẹ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ní anfaani láti dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbakugba ti mo ba nlọ si Spania, ng ó tọ̀ nyin wá: nitori mo nireti pe emi o ri nyin li ọ̀na àjo mi, ati pe ẹ o mu mi já ọ̀na mi nibẹ̀ lati ọdọ nyin lọ, bi mo ba kọ kún fun ẹgbẹ nyin li apakan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
mo gbèrò láti se bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí orílẹ̀ èdè Sípáníà. Èmi yóò bẹ̀ yín wò ní ọ̀nà ìrìnàjò mi, lẹ́yìn tí a bá sì gbádùn ara wa fún ìgbà díẹ̀, ẹ ó kún mi ọ́wọ́ nínú ìrìnàjò mi láti dé ibẹ̀.