Romans 15:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n fi inú dídùn ṣe é, ó sì jẹ wọ́n lógún láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí bí àwọn tí kì í ṣe Juu ti pín ninu àwọn nǹkan ti ẹ̀mí ti àwọn onigbagbọ láti Jerusalẹmu, ó yẹ kí wọ́n kà á sí iṣẹ́ ìsìn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹlu ohun ìní wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitõtọ ifẹ inu rere wọn ni; ajigbese wọn ni nwọn sá ṣe. Nitori bi o ba ṣepe a fi awọn Keferi ṣe alajọni ninu ohun ẹmí wọn, ajigbese si ni wọn lati fi nkan ti ara ta wọn lọrẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń se èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbésè fún wọn. Nítorí bí ó bá se pé a fi àwọn aláìkọlà se alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ.