Romans 15:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí fún àtikọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣe kọ ohunkohun tí a ti kọ tẹ́lẹ̀, ìdí rẹ̀ ni pé kí ìgboyà ati ìwúrí tí Ìwé Mímọ́ ń fún wa lè fún wa ní ìrètí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ fun kíkọ wa, pe nipa sũru ati itunu iwe-mimọ́ ki a le ni ireti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ohun gbogbo tí a kọ nígbà àtijọ́ ni a kọ láti fi kọ́ wa, kí àwa lè ní ìrètí nípa sùúrù àti ìtùnú èyí tí ó wá láti inú ìwé mímọ́.