Romans 16:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kí Andironiku ati Junia, àwọn ìbátan mi tí a jọ wà lẹ́wọ̀n. Olókìkí ni wọ́n láàrin àwọn òjíṣẹ́ Kristi, wọ́n sì ti di onigbagbọ ṣiwaju mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kí Androniku ati Junia, awọn ibatan mi, ati awọn ẹgbẹ mi ninu tubu, awọn ẹniti o ni iyìn lọdọ awọn Aposteli, awọn ẹniti o ti wà ninu Kristi ṣaju mi pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ kí Áńdíróníkúsì àti Júníásì, àwọn ìbátan mi tí wọ́n wà ní ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi. Àwọn wọ̀nyí ní ìtayọ láàrin àwọn àpósítélì, wọ́n sì ti wà nínú Kírísítì sáájú mi.