Romans 2:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí àwáwí kankan fún ọ, ìwọ tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́. Nǹkan gan-an tí ò ń torí rẹ̀ dá ẹlòmíràn lẹ́jọ́ ni o fi ń dá ara rẹ lẹ́bi. Nítorí ìwọ náà tí ò ń dáni lẹ́jọ́ ń ṣe àwọn nǹkan gan-an tí ò ń dá ẹlòmíràn lẹ́bi fún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORINA alairiwi ni iwọ ọkunrin na, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ ti ndajọ: nitori ninu ohun ti iwọ nṣe idajọ ẹlomiran, iwọ ndá ara rẹ lẹbi; nitori iwọ ti ndajọ nṣe ohun kanna.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, aláìríwí ni ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó jẹ́ tí ń dáni lẹ́jọ́: nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣe ìdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi; nítorí ìwọ tí ń dájọ́ ń ṣe ohun kan náà nínú èyí tí ìwọ ń dáni lẹ́jọ́.