Romans 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ láì lófin, láì lófin náà ni wọn yóo kú. Gbogbo àwọn tí wọ́n mọ Òfin, tí wọ́n sì dẹ́ṣẹ̀, òfin náà ni a óo fi ṣe ìdájọ́ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori iye awọn ti o ṣẹ̀ li ailofin, nwọn ó si ṣegbé lailofin: ati iye awọn ti o ṣẹ̀ labẹ ofin, awọn li a o fi ofin dalẹjọ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ó sẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dálẹ́jọ́;