Romans 2:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Irú àwọn wọnyi fihàn pé a ti kọ iṣẹ́ ti Òfin sinu ọkàn wọn. Ẹ̀rí ọkàn wọn ń ṣiṣẹ́ ninu wọn: àwọn èrò oríṣìíríṣìí tí ó wà ninu wọn yóo máa dá wọn láre tabi kí ó máa dá wọn lẹ́bi,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ẹniti o fihan pe, a kọwe iṣẹ ofin si wọn li ọkàn, ti ọkàn wọn si njẹ wọn lẹri, ti iro wọn larin ara wọn si nfi wọn sùn tabi ti o ngbè wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsìnyí.