Romans 2:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn láti jẹ́ Juu tòótọ́ jẹ́ ohun àtinúwá; ìkọlà jẹ́ nǹkan ti ọkàn. Nǹkan ti ẹ̀mí ni, kì í ṣe ti inú ìwé. Ìyìn irú ẹni bẹ́ẹ̀ wà lọ́dọ̀ Ọlọrun, kì í ṣe ọ̀dọ̀ eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Ju ti inu ni Ju, ati ikọla ti ọkàn, ninu ẹmi ni, kì iṣe ti ode ara; iyìn ẹniti kò si lọdọ enia, bikoṣe lọdọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.