Romans 5:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ikú Ọmọ Ọlọrun bá sọ àwa tí a jẹ́ ọ̀tá Ọlọrun di ọ̀rẹ́ rẹ̀, nígbà yìí tí a wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun tán, ajinde ọmọ rẹ̀ yóo gbà wá là ju tàtẹ̀yìnwá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi, nigbati awa wà li ọtá, a mu wa ba Ọlọrun làja nipa ikú Ọmọ rẹ̀, melomelo, nigbati a là wa ni ìja tan, li a o gbà wa là nipa ìye rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ bí, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀.