Romans 5:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn kì iṣe bi ẹ̀ṣẹ bẹ̃ si li ẹ̀bun ọfẹ. Nitori bi nipa ẹ̀ṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ kú, melomelo li ore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹ̀bun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jésù Kírísítì, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀.