Romans 5:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kì í ṣe ẹnìkan tí ó dẹ́ṣẹ̀ ni Ọlọrun ń wò kí ó tó ta àwọn eniyan lọ́rẹ. Ẹnìkan ló fa ìdájọ́ Ọlọrun. Ẹ̀bi ni a sì rí gbà ninu rẹ̀. Ṣugbọn àánú tí Ọlọrun fún wa dípò ọpọlọpọ aṣemáṣe wa, ìdáláre ni ó yọrí sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kì isi ṣe bi nipa ẹnikan ti o ṣẹ̀, li ẹ̀bun na: nitori idajọ ti ipasẹ ẹnikan wá fun idalẹbi ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ ti inu ẹ̀ṣẹ pupọ wá fun idalare.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kì í ṣe bí nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà: Nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre,