Romans 5:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ikú bá torí òfin tí ẹnìkan rú jọba lé wa lórí, àwọn tí ó ti gba ibukun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì gba ìdáláre lọ́fẹ̀ẹ́, yóo ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: wọn óo jọba, wọn óo sì yè pẹlu àṣẹ ẹnìkan, Jesu Kristi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ ọkunrin kan ikú jọba nipasẹ ẹnikanna; melomelo li awọn ti ngbà ọ̀pọlọpọ ore-ọfẹ ati ẹ̀bun ododo yio jọba ninu ìye nipasẹ ẹnikan, Jesu Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ bí nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin kan, ikú jọba nípasẹ̀ ẹnìkan náà; mélòó mélòó ni àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bùn òdodo yóò jọba nínú ìyè nípasẹ̀ ẹnìkan, Jésù Kírísítì.